Académique Documents
Professionnel Documents
Culture Documents
“OGBE YEKU, BABA AMULU, OGBO ATO, AWO EDAN A DA FUN EDAN , KI EDAN ISE KU,
AGBA IWORO A KU KATA KATA.
OLOWO ILA TIKO AWON KO GBODO KO IGBIN ADA FUN KINIUN OMO ARITO GBAJU TI
MBE NI A PENYAJE OMO ERANKO.
IFA NI ORI ENIKAN TI KO NI IGBA TI KO NI AWO TI GBOGBO ENIA ATI AWON ARA ILE RE
NPE NI OLORI BURU BURU TI NWON SI NFI SE ELEYA; IFA NI OLUWARE YIO DI ENIA NLA
LEHIN OLA ATI PE YIO SI MA RAN ORO.
NI AKOKO LAI LAI GBOGBO AWON ERANKO NI IMA RE KINIUN JE, BI O BA SUN SILE,
NWON A MA GUN LORI NWON KO SI BIKITA FUN; KINIUN WA MURA OTO AWON
BABALAWO LO, O SI BERE PE KIN NI OHUN TI ON LE SE TI ON FI LE NI IYI ATI OWO LOJU
AWON EGBE ON? AWON BABALAWO NI KI ORUBO KEREGBE OMI KAN, ERU, KUMO
META, EWE IFA EWE OWO NWON NI KI OGBO EWE IFA NA SINU OMI, KI O DA ERU NA
SI, KI O SIGBE MU, ATI PE BI O BA DUBU LE SI IBI KU IBI KI O MA TO YI ARA KA. NIGBA
TI KINIUN SI TI SE EYI TAN, BI O BA MA SUN, YIO SI TO YI ARA RE KA, BI AWON ERANKO
BASI FE LATI MA GUN LORI BI TI ATEHIN WA, BINWON BA TI DA ITO RE KOJA NWON A
SUBU LULE, NWON A SI DI OKU, BAYI NI KINIUN DI ENI ERU LARIN AWON ERANKO,
BINWON BA SI GBO OHUN RE, ERU A BA WON, NWON A SI MA GBON RIRI. LATI IGBA NA
NIKINIUN TI MA NKE PE AFI ENIA, AFI EMI, AFI OLORUN”
(yoruba)